تجاوز إلى المحتوى

Ipin Itan Anabi.

32 lessons · Select a question to read the answer

Your progress in this topicTrack completed lessons on this device
Choose how to study:
1Ibeere 1: Ki ni ìdílé Anabi wa Muhammad (ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a)?

Idahun- Oun ni Muhammad ọmọ Abdullah ọmọ Abdul Muttalib ọmọ Hāshim, ti Hāshim wa lati idile Quraysh, ti Quraysh wa lati iran larubawa, ti larubawa si jẹ arọmọdọmọ Ismā‘īl ti Ismā‘īl si jẹ ọmọ Ibrāhīm, ki ikẹ ati ọla ti o lọla julọ maa ba oun ati Anabi wa.

Open lesson
2Ibeere 2: Ki ni orukọ iya Anabi wa (ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a)?

Idahun- Āminatu ọmọ Wahb.

Open lesson
3Ibeere 3: Ìgbà wo ni baba rẹ ku?

Idahun- Baba rẹ ku ni Mẹdina, ti oun si wa ni oyún, ti wọn o tii bi i (ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a).

Open lesson
4Ibeere 4: Ìgbà wo ni wọn bi Anabi (ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a)?

Idahun- Ni ọdún eleerin, ni ọjọ Monday (aje) ninu oṣù Rabī‘ul awwal.

Open lesson
5Ibeere 5: Ilu wo ni wọn ti bi i?

Idahun- Ni Mẹka.

Open lesson
6Ibeere 6: Awọn wo ni awọn ti wọn fun un ni ọyàn ati awọn ti wọn tọju rẹ lẹyin iya rẹ.

Idahun- Ẹrubinrin ti baba rẹ sọ di ọmọluabi ti n jẹ Ummu Ayman.

- Ẹrubinrin ti ọmọ-ìyá baba rẹ Abū Lahab sọ di ọmọluabi ti n jẹ Thuwaybah.

- Halīmatu As-Sa‘diyyah.

Open lesson
7Ibeere 7: Ìgbà wo ni ìyá rẹ ku?

Idahun- Iya rẹ ku nígbà tí o wa ni ọmọ ọdun meji, ti baba baba rẹ Abdul Muttalib si gba a tọ.

Open lesson
8Ibeere 8: Ta ni o gba a tọ lẹyin iku baba baba rẹ Abdul Muttalib?

Idahun- Baba baba rẹ ti n ṣe Abdul Muttalib ku nígbà tí o wa ni ọmọ ọdun mẹjọ, ti ọmọ-ìyá baba rẹ Abū Tālib si gba a tọ.

Open lesson
9Ibeere 9: Ìgbà wo ni o ṣe irin-ajo pẹlu ọmọ-ìyá baba rẹ lọ si ilu Shām?

Idahun- O ṣe irin-ajo pẹlu ọmọ-ìyá baba rẹ lọ si Shām ti ọjọ ori rẹ si jẹ ọdun mejila.

Open lesson
10Ibeere 10: Ìgbà wo ni irin-ajo rẹ eleekeji wáyé?

Idahun- Irin-ajo rẹ ẹlẹẹkeji wáyé nipa òwò kan ti o ṣe pẹlu owó Khadījah - ki Ọlọhun yọnu si i -, nígbà tí o wa ṣẹri pada, o- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a- wa fẹ ẹ (Khadījah).

Open lesson
11Ibeere 11: Ìgbà wo ni awọn Quraysh tun Ka‘bah mọ?

Idahun- Awọn Quraysh tun Ka‘bah mọ nígbà tí ó wà ní ọmọ ọdun marunlelọgbọn.

Wọn si fi ṣe adajọ nígbà tí wọn yapa nipa ẹniti yio gbe okuta dudu si aaye rẹ, ni o wa gbe e si inu aṣọ, o wa pa idile kọọkan laṣẹ ki wọn mu eti kọọkan nibi aṣọ náà, ti wọn si jẹ idile mẹẹrin, nígbà tí wọn wa gbe e de aaye rẹ, o fi ọwọ rẹ gbe e si ibẹ (ki ikẹ ati ọla maa ba a).

Open lesson
12Ibeere 12: Ọmọ ọdun melo ni i nígbà tí wọn gbe e dide? Ta ni wọn si ran an si?

Idahun- Ọjọ ori rẹ jẹ ogoji ọdun, wọn si gbe e dide si gbogbo eeyan patapata ni Olufunni niroo idunnu ati olukilọ iya fun ni.

Open lesson
13Ibeere 13: Ki ni akọkọ nkan ti Wahyi (Imisi) bẹrẹ pẹlu rẹ?

Idahun- Ala ododo, ko waa nii la ala kankan ayaafi ki o wa gẹgẹ bii imọlẹ owurọ.

Open lesson
14Ibeere 14: Bawo ni ìṣesí rẹ ṣíwájú Wahyi (Imisi)? Àti pé ìgbà wo ni Wahyi sọkalẹ fun un ni igba akọkọ?

Idahun- O jẹ ẹni tí maa n ṣe ijọsin fun Ọlọhun ninu kòtò Hirā ti o si maa mú èsè dání fun un.

Wahyi (imisi) si sọkalẹ fun un, nígbà tí o wa nínú koto naa lẹniti n ṣe ijọsin.

Open lesson
15Ibeere 15: Kí ni akọkọ nkan ti Ọlọhun sọkalẹ ninu Al-Qur'āni?

Idahun- Gbolohun Ọba ti ọla Rẹ ga pe: Ké (al-Ƙur’ān) pẹ̀lú orúkọ Olúwa rẹ, Ẹni tí Ó dá ẹ̀dá. 1 Ó ṣẹ̀dá ènìyàn láti ara ẹ̀jẹ̀ dídì. 2 Ké e. Olúwa rẹ ni Alápọ̀n-ọ́nlé jùlọ. 3 Ẹni tí Ó fi ìmọ̀ nípa gègé ìkọ̀wé mọ ènìyàn. 4 Ó fi ìmọ̀ tí ènìyàn kò mọ̀ mọ̀ ọ́n. 5 [Suuratul Alaq: 1 - 5]

Open lesson
16Ibeere 16: Ta ni ẹni akọkọ ti o ni igbagbọ si iranṣẹ rẹ?

Idahun: Nínú awọn ọkunrin: Abubakr' As-sideeq, ninu awọn obinrin: Khadijah ọmọ Khuwaylid, ninu awọn ọmọ keekeeke: Aliyy ọmọ Abuu Taalib, ninu awọn ẹru ti o ti di ọmọ: Zaid ọmọ Haaritha, ninu awọn ẹru: Bilaal Al-Habashiy (ki Ọlọhun yọnu si wọn) ati awọn miran.

Open lesson
17Ibeere 17: Bawo ni ipepe sinu Isilaamu ṣe waye?

Idahun: Ipepe waye ni kọkọ fun nǹkan bíi ọdún mẹta, lẹyin naa ni o (ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a) paṣẹ pẹlu ipepe gbangba.

Open lesson
18Ibeere 18: Kí ni iṣesi Anabi (ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a) ati awọn ti wọn gba a gbọ wa lẹyin ti ipepe gbangba waye?

Idahun – Àwọn ọṣẹbọ fi ṣuta kan an gan ati awọn Musulumi, titi ti o fi yọnda fun awọn olugbagbọ ododo lati ṣe hijira lọ si ọdọ Najaashi ni ilẹ Habasha.

Awọn ẹlẹbọ si fi ẹnu kò lati fi ṣuta kan an, ati lati pa a (ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a). Ọlọhun wa dáàbò bo o, ti O si rọgbayika rẹ pẹlu ẹgbọn baba rẹ tii ṣe Abuu Taalib lati le baa daabo bo o kuro lọwọ wọn.

Open lesson
19Ibeere 19: Ta ni ẹniti o ku ni ọdun ẹlẹẹkẹwaa lati igba ti wọn ti gbe e (ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a) dide?

Idahun- Ẹgbọn baba rẹ tii ṣe Abuu Taalib ati iyawo rẹ tii ṣe Khadeejah (ki Ọlọhun yọnu si i) kú.

Open lesson
20Ibeere 20: Igba wo ni Israa' ati Mi'raaj waye?

Idahun: O wa ni ọmọ ọdun àádọ́ta. Ọlọhun si ṣe awọn irun márùn-ún ni ọranyan le e lori.

Idahun: Israa': Lati Mọṣalaṣi abeewọ lọ si Mọṣalaṣi Aq'saa.

Mi'raaj: Oun waye lati Mọṣalaṣi Aq'saah titi lọ si Sid'ratil mun'taha.

Open lesson
21Idahun 21: Bawo ni Anabi (ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a) ṣe n pe awọn eeyan ni ita makkah.

Idahun: O maa n ṣe ipepe fun awọn ara ilẹ Taaif, o si maa n fi ara rẹ han wọn ni àwọn aaye ipadepọ awọn eeyan titi ti awọn Ansọọr fi de lati ilu Mẹdina ti wọn si gba a gbọ, wọn si tun gba ọwọ rẹ ni ti adehun lati ran an lọ́wọ́.

Open lesson
22Ibeere 22: Igba melo ni Anabi (ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a) fi wa ni Mẹka ti n pe awọn eeyan?

Idahun- O lo ọdun mẹtala nibẹ.

Open lesson
23Ibeere 23: Nibo ni Anabi (ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a) ṣe hijira lọ?

Idahun: O ṣe e lati Makkah lọ si Mẹdina.

Open lesson
24Ibeere 24: Igba melo ni o lo ni Mẹdina?

Idahun: Ọdun mẹ́wàá ni in.

Open lesson
25"Ibeere ẹlẹẹkarundinlọgbọn: Ki ni nnkan ti wọn ṣe ni ọranyan le e lori ni Mẹdina ninu awọn ofin Isilaamu? "

"Idahun- wọn ṣe yiyọ zakah ni ọranyan le e lori, ati aawẹ gbigba, ati lilọ si ile oluwa, ati jijagun si oju-ọna Ọlọhun, ati pipe irun, ati eyi to yatọ si i ninu awọn ofin Isilaamu.

Open lesson
26"Ibeere ẹlẹẹkẹrindinlọgbọn: Ki ni awọn to pataki ninu awọn ogun rẹ ti o kopa nibẹ -ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-? "

"Idahun- ogun badari nla."

."Ogun uhud."

"Ogun Al-Ahzâb "

Ogun ṣiṣi Mẹka"

Open lesson
27"Ibeere ẹlẹẹkẹtadinlọgbọn: ki ni eyi to kẹyin ninu nnkan ti wọn sọkalẹ ninu Kuraani? "

"Idahun- ọrọ Rẹ -Ọba ti ọla Rẹ ga-: " "{Ẹ bẹ̀rù ọjọ́ kan tí wọ́n máa da yín padà sí ọ̀dọ̀ Allāhu. Lẹ́yìn náà, Wọ́n máa san ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan ní ẹ̀san ní ẹ̀kún rẹ́rẹ́ (nípa) ohun tí ó ṣe níṣẹ́. Wọn kò sì níí ṣàbòsí sí wọn 281}. " [Suuratul-Baqarah: 281].

Open lesson
28"Ibeere ẹlẹẹkejidinlọgbọn: Ìgbà wo ni Anabi -ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- kú? Ati pe mélòó ni ọjọ ori rẹ? "

"Idahun- o ku ni oṣu Robii’ul Awwal, ni ọdun ẹlẹẹkọkanla ni ọdun hijra, ti o si jẹ ọmọ ọdún mẹtalelọgọta.

Open lesson
29"Ibeere ẹlẹẹkọkandinlọgbọn: Dárúkọ awọn iyawo Anabi -ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ? "

"1- Khadijah ọmọ Khuwailid -ki Ọlọhun yọnu si i- "

"2- Saodah ọmọ Zam'ah- ki Ọlọhun yọnu si i- "

"3- A'ishah ọmọ Abu Bakr -ki Ọlọhun yọnu si i- "

4- Hafsoh ọmọ Umar -ki Ọlọhun yọnu si i- "

"5- Zainab ọmọ Khuzaimoh -ki Ọlọhun yọnu si i- "

"6- Ummu Salamoh Hind ọmọ Abu Umayyah- ki Ọlọhun yọnu si i- "

"7- Ummu Habibah Romlah ọmọ Abu Sufyan- ki Ọlọhun yọnu si i- "

"8- Juwayriyah ọmọ Harith- ki Ọlọhun yọnu si i- "

"9- Maimuunah ọmọ Haarith- ki Ọlọhun yọnu si i- "

10- Sofiyyah ọmọ Hayiy- ki Ọlọhun yọnu si i- "

"11- Zainab ọmọ Jahsh- ki Ọlọhun yọnu si i-"

Open lesson
30Ibeere 30: Awọn wo ni awọn ọmọ rẹ (ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a)?

Awọn ọkunrin mẹta ni wọn:

Qāsim, oun si ni wọn fi maa n da a pe.

Ati Abdullāhi.

Ati Ibrāhīm.

Awọn Obinrin:

Fatima

Rukayyah

Ummu kulthuum

Zaynab

Gbogbo ọmọ rẹ pata, ati ara Khadījah ni wọn ti wa - ki Ọlọhun yọnu si i - ayaafi Ibrāhīm, gbogbo wọn lo si ku ṣaaju rẹ ayaafi Fātimah to ku lẹyin rẹ lẹyin oṣu mẹfa.

Open lesson
31Ibeere 31: Darukọ apakan awọn iroyin Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ti o jẹ ti ṣiṣẹda rẹ?

O jẹ - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ẹniti o wa ni iwọntun-wọnsi ninu awọn ọkunrin ni, ko kuru ko si ga, amọ o wa laarin iyẹn, o jẹ ẹniti o funfun ti pupa dà papọ mọ ọn - ki ikẹ ati ọla maa ba a- o jẹ ẹniti irungbọn rẹ pọ, ti oju rẹ mejeeji si fẹ̀, ti ẹnu rẹ si tóbi, irun rẹ dudu gan-an, ejika rẹ mejeeji si tóbi, oorun rẹ si dun, ati èyí tí o yatọ si iyẹn ninu ṣiṣẹda rẹ to rẹwa (ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a)

Open lesson
32Ibeere 32: Lori ki ni Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - fi awọn ijọ rẹ le?

Idahun- O fi ijọ rẹ silẹ - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sori oju-ọna ti o funfun, ti oru rẹ da bi ọsan rẹ, ẹnikan o si nii yẹ kuro nibẹ ayaafi ẹni iparun, ko si fi daadaa kan silẹ ayaafi ko juwe ijọ rẹ si i, ko si tun fi aburu kan silẹ ayaafi ki o kọ fun wọn kuro nibẹ.

Open lesson